Àṣamọ̀
Orin jẹ́ ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ kan pàtàkì láwùjọ Yorúbà. Ìdí ní pé lọ́pọ̀ ìgbà orin yìí ní wọ́n máa ń lò láti fí tún àwùjọ ṣe. Bí tolórí–tẹlẹ́mù bá hùwà ìbàjẹ́ láwùjọ, àwọn ọ̀kọrin a fi orin sín wọn nígbẹ́rẹ́ ìpàkọ́, kí àtúnṣé ìwà bá a lè wáyé. Ohun tí ó jẹ wá lógún nínú pépà yìí ní èdè bí òdì-àdá tí Habeeb Ọmọlálọmí ń lò nínú àṣàyàn orin rẹ̀. Èdè bí òdì àdá ni nígbà tí ènìyàn bá ń ṣàmúlò èdè ní àdórikòdì. Kàkà kí a gbọ́ èdè tó jinlẹ̀ tó ń fi ìwà Ọmọlúàbí hàn láwùjọ lẹ́nu Habeeb Ọmọlálọmí, èdè àbùkù tó ń fi ìwà ìpánle rẹ̀ hàn ló ń jẹ jáde nínú àwọn orin rẹ̀. Bí Habeeb Ọmọlálọmí ṣe ń lo àdoríkòdì èdè yìí kò ní jẹ́ ká dá nìkan rìn ní àwùjọ. Fún ìdí èyí, a ṣe àfihàn bí ó ṣe lo èdè bí òdì-àdá nínú àṣàyàn orin rẹ̀. Kíkàn sí àwọn ẹ̀rọ tọ́rọ́fọ́nkálé pẹ̀lú kíka àwọn àkọsílẹ̀ lórí èdè àti orin ni a lò láti fi kó détà jọ. Ìpèníjà wa ni ọ̀rọ̀ báyéṣerí ní àwùjọ òde-òní, nípa bí akọrin ìgbàlódé ṣe ń lo èdè àdoríkòdì. Iṣẹ́ àkànṣe yìí tún ṣe ìtanijí lórí bí àwọn ọ̀kọrin tí ń kẹ́rẹ̀ bá ṣíṣe àmúlò èdè nítorí àtijẹ wọn gẹ́gẹ́ bí arebipa. Tíọ́rì ìmọ̀ ìbára-ẹni-gbépọ̀ láwùjọ tí ó tẹ̀lé èrò báyéṣerí bóyá ìdàgbàsókè tó ń bá àwùjọ ló ń ṣe àkóbá bí àwọn nǹkan ṣe ń yípadà ní àkókò kan ni ti dáadáa tàbí èyí tó kù díẹ̀ káàtó. Bótitọ́ kan kò sí mọ́ bótigbà ló kù. Àbájáde pépà yìí ní pé onílùú kó ní fẹ́ kó tú, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìṣàmúlò èdè nínú orín fẹsẹ̀múlẹ̀. A dábàá pé kí àpérò máa wáyé ní gbogbo ìgbà láti lè jẹ́ kí àwùjọ mọ̀ pé arebipa lásán ni ọ̀kọrin ìgbàlódé.
Kókó Ọ̀rọ̀: Èdè, Orin, Ọ̀kọrin, Ìbánisọ̀rọ̀, Tíọ́rì ìmọ̀ ìbára-ẹni-gbépọ̀ láwùjọ