Àsͅamòͅ
Onírúurú ìpèdè àti òͅròͅ àwoͅn Yorùbá ló ti sͅàfihàn bí oúnjeͅ sͅe jéͅ pàtàkì sí àwùjoͅ oͅmoͅnìyàn, ní pàtàkì àwùjoͅ Yoùbá. Àwoͅn òͅròͅ bí oúnjeͅ lòͅréͅ àwòͅ, bí ebi bá ti kúrò nínú ìsͅéͅ, ìsͅéͅ bùsͅe, nnkan okun inú là á fí gbé tòde. Ìpèdè wòͅnyí n sͅe atótónu àwoͅn ipòͅ tí Yorùbá to oúnjeͅ jíjeͅ sí, torí pé nínú orísͅirísͅi nnkan tí a máa n jeͅ sínú ara wa ni oúnjeͅ wà, tí ó n gba eͅnu wa woͅlé sí ikùn fún ìlera, àlàáfíà, okun ara, agbára àti ìdàgbàsókè àwoͅn èͅyà ara ènìyàn. Orísͅirísͅi oúnjeͅ ìbílèͅ tí Yorùbá féͅràn ní jíjeͅ kí àwoͅn oúnjeͅ abóyìnbó gòkè odò tó dé àwùjoͅ wa. Àkóbá tí kò kéré ni òͅpòͅ àwoͅn oúnjeͅ ilèͅ òkèèrè tí à n jeͅ n sͅe fún ìlera ara wa torí pé a ti koͅ àwoͅn oúnjeͅ Yorùbá tó kún fún èròjà nnkan asͅaralóore sílèͅ ní jíjeͅ. Láti mú àwoͅn oúnjeͅ wòͅnyí bòͅ sípò tí wóͅn wà téͅlèͅ kí àwoͅn oúnjeͅ ìgbàlódé tó woͅ àwùjoͅ wa ni a sͅe sͅàgbékalèͅ isͅéͅ ìwádìí yìí èyí tí ó le mú kí á bóͅ nínú àwoͅn orísͅirísͅi àwoͅn àìsàn tí à n kó nípasèͅ àwoͅn oúnjeͅ ìgbàlódé tí à n jeͅ. Àsͅàyàn àwoͅn oúnjeͅ asͅaralóore Yorùbá tó ti méͅrí bíi èkuru, móͅín-móͅín oníjógí, móͅín-móͅín elépo, sͅàgbà, àlápà, sͅapala, móͅsà ni iséͅ yìí dálé lórí. Oͅgbóͅn ìsͅèwádìí tí a lò fún isͅéͅ yìí ni ìfòͅròͅ-wá-ni-lénu wò pèͅlú sͅísͅe àyèͅwò àkòrí isͅéͅ tó ròͅ móͅ àkòrí isͅéͅ yìí tí àwoͅn onímòͅ ti sͅisͅéͅ lé lórí. Lóòótóͅ ni àwoͅn onímò lórísͅirísͅi ti gbé ìdánilékóͅ kalèͅ lórí onírúurú oúnjeͅ abínibí Yorùbá, sͅùgbóͅn oͅwóͅjà isͅéͅ woͅn kò tí ì dé orí àwoͅn oúnjeͅ ìbílèͅ tí a sͅe ìwádìí lé lórí. Èyí ni àlàfo tí isͅéͅ ìwádìí yìí féͅ dí.
Kókó òͅrò:- A` sͅàyàn oúnjeͅ, àwùjoͅ Yorùbá, méͅrı́, oúnjeͅ abı́nibı́, asͅaralóore