ÀṢAMỌ`
Ohun tí ó jẹ́ iṣẹ́ ìwádìí yìí lógún ni àwọn ọsẹ́ àti àyípadà tí ọ̀làjú ti se fún àṣà oge síse láàrin ẹ̀yà Yorùbá. Àwọn ọ̀nà tí a sì gbà gbé iṣẹ́ ìwádìí yìí kalẹ̀ ní ìlànà ìfọ̀rọ̀wáni-lẹ́nuwò àti s̩ís̩e àyẹ̀wò oníruurú ìwé lórí ohun tí àwọn onímọ̀ ti sọ nípa àwo̩n kókó tí ó jẹmọ́ àkórí isẹ́ yìí. Nínú àwọn kókó tí iṣẹ́ ìwádìí yìí yàn-nà-ná rẹ̀ ni ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ oge s̩ís̩e , orísirísí ò̩nà tí à ń gbà se oge àyípadà tí ó ti bá oge síse, ohun tí ọ̀làjú jẹ́ gan-an, àwọn ohun tí Yorùbá máa ń lò láti fi s̩e oge, àwọn oge síse tí àwọn obìnrin, oge síse tí àwọn ọkùnrin, àwọn oge síse tí ó jẹ tọkùnrin- tobìnrin, àwọn àtọ̀únrínwà oge síse. Iṣẹ́ ìwádìí fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn àyípadà ti bá oge síse láti ipasẹ̀ ọ̀làjú tí ó ti wọnú àwùjọ Yorùbá, bẹ́ẹ̀ ni ó se àfihàn ọṣẹ́ tí ọ̀làjú yìí ti se nínú oge síse ẹ̀yà Yorùbá. Nínú wọn ni: irun ojú lílẹ̀ tí ó lè se òkùnfà ojú fífọ́ àti ojú dídùn, tàtúù ún tí ó lè di egbò sí ara, irun dídì olówó iyebíye tí ó ń mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin wọ́nu ẹgbẹ́kẹ́gbé èyí tí ó lè da ilé wọn ru. Isẹ́ ìwádìí yìí, dábàá àwo̩n ò̩nà àbáyo kúrò nínú èérí ti òlàjú ti mu bá àsà yìí pé ki àwon olórí ẹ̀sìn máa tẹnu mọ́ ìwàásù nípa ogekóge àti àwọn nǹkan búburú tí ó lè yọrí sí ní àwọn ilé ìjọsìn wa gbogbo. Kí àwùjọ àti ìjọba máa se àfihàn àwọn ìpalára tí àwọn ogekóge máa ń fà.
Òkùté̩ Ọ` rọ̀: Àyípadà àkórí, Ọ` làjú Àtọ̀únrìnwá, Ọsẹ́, Ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́, Iyebíye.