Logo Lanfrica
  • Accueil
  • Atlas
  • Analyses
  • Documentation
  • Sign in

© 2026 Lanfrica. Tous droits réservés. Tous les droits d'auteur des ressources affichées sur le site Web Lanfrica appartiennent aux détenteurs de droits d'auteur d'origine, sauf indication contraire explicite.

Àgbéyẹ̀wò Ìlò-Èdè Nínú Orin Ìbílẹ̀ Ìlọrin

Domaine:

natural language processing
Créateur:
Hak
Éditeur:
Uni
Hôte:
Ọ̀kan pàtàkì tí kò ṣe é fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn lára ẹ̀ka tí lítíréṣọ̀ alohùn Yorùbá pín sí ni orin jẹ́. Bárakú sì ní ọ̀rọ̀ orin láwùjọ ọmọ ènìyàn pàápàá jù lọ àwọn Yorùbá nítorí pé onírúurú ààyè ni orin ti máa ń jẹ jáde nínú ìgbésí-ayé wọn lójoojúmọ́. Bí àwọn akọrin àwùjọ bá sì ń ṣiṣẹ́ ọnà wọn, ìjìnlẹ̀ èdè tó jinná ni wọ́ n fi máa ń gbé e jáde tí yóò sì máa ṣàfihàn bí irú àwọn akọrin bẹ́ ẹ̀ ṣe gbọ́ èdè àti ìmọ̀ nípa àṣà àwùjọ tó ti ń kọrin nítorí pé ìpohùn ìbílẹ̀ èyí tí orin jẹ́ ọ̀ kan pàtàkì lára wọn dà gẹ́gẹ́ bí àwògbè tàbí díńgí tí a fi ń ríran rí àwùjọ. Ìlò-èdè tó jinná kò sì ṣe é fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn kí àgbékalẹ̀ orin wọ̀nyẹn lè rídìí jòkó dáadáa kí wọ́n sì lè wu etí í gbọ́. Nínú iṣẹ́ yìí, a ṣe àgbéyẹ̀wò àtí àtúpalẹ̀ díẹ̀ lára àwọn ọnà-èdè tó ṣúyọ nínú àṣàyàn orin ìbílẹ̀ Yorùbá Ìlọrin bíi dàdàkúàdà, bàlúù, wákà, kèǹgbè, sẹnwẹlẹ, kàkàkí/bẹ̀ ǹbẹ́ , Orin ọlọ́ mọ-ọba Ìlọrin,orin agbè àti àwọn mìíràn. Lára àwọn ọnà-èdè tí a gbéyẹ̀ wò ni àwítúnwí, àfiwé, ìjẹyọ ẹ̀ ka-èdè, àyálò-èdè àti ipa ‘Creole’ nínú orin ìbílẹ̀ Ìlọrin. Iṣẹ́ yìí ṣàfihàn pé iṣẹ́ ọpọlọ tó jinná ni orin kíkọ àti pé àwọn ọnà-èdè tó máa ń ṣodo sínú wọn lóríṣiríṣi ní iṣẹ́ tí kálukú wọn ń jẹ́ láti túdìí òkodoro nípa àṣà, ìṣe àti èdè àwùjọ tí onírúurú àwọn orin náà ti ń jáde

Visit

doi.org

Languages

Yoruba

Licenses

https://creativecommons.org/licenses/by-nc/4.0

Similaires

Àgbéyẹ̀wò Ipa Èdè, Àṣà, àti Lítíréṣọ̀ Yorùbá Nínú ọ̀gbagadè Ìtàn Orílẹ̀-èdè NàìjíríàÈDÈ BÍ ÒDÌ-ÀDÁ FÚN ÌBÁNISỌ̀RỌ̀ NÍNÚ ÀWỌN ÀṢÀYÀN ORIN HABEEB ỌMỌLÁLỌMÍ

Àgbéyẹ̀wò Ipa Èdè, Àṣà, àti Lítíréṣọ̀ Yorùbá Nínú ọ̀gbagadè Ìtàn Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà

Ede, asa ati litireso je mayami eta-oko to n safihan idanimo awon eniyan kan. Ni orile-ede Naijiria,

ÈDÈ BÍ ÒDÌ-ÀDÁ FÚN ÌBÁNISỌ̀RỌ̀ NÍNÚ ÀWỌN ÀṢÀYÀN ORIN HABEEB ỌMỌLÁLỌMÍ

Àṣamọ̀

&l